Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 46:14-26 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ó ní, “Ẹ kéde ní Ijipti,ẹ polongo ní Migidoli, ní Memfisi ati ní Tapanhesi.Ẹ wí pé, ‘Ẹ gbáradì kí ẹ sì múra sílẹ̀,nítorí ogun yóo run yín yíká.

15. Kí ló dé tí àwọn akọni yín kò lè dúró?Wọn kò lè dúró nítorí péOLUWA ni ó bì wọ́n ṣubú.’

16. Ogunlọ́gọ̀ yín ti fẹsẹ̀ kọ, wọ́n sì ṣubú,wọ́n wá ń wí fún ara wọn pé,‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan wa,ati sí ilẹ̀ tí wọn gbé bí wa,nítorí ogun àwọn aninilára.’

17. “Ẹ pa orúkọ Farao, ọba Ijipti dà,ẹ pè é ní, ‘Aláriwo tí máa ń fi anfaani rẹ̀ ṣòfò.’

18. Ọba, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,fi ara rẹ̀ búra pé, bí òkè Tabori ti rí láàrin àwọn òkè,ati bí òkè Kamẹli létí òkun,bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan tí yóo yọ si yín yóo rí.

19. Ẹ di ẹrù yín láti lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀yin ará Ijipti!Nítorí pé Memfisi yóo di òkítì àlàpà,yóo di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo máa gbé ibẹ̀.

20. Ijipti dàbí ọmọ mààlúù tí ó lẹ́wà,ṣugbọn irù kan, tí ó ti ìhà àríwá fò wá, ti bà lé e.

21. Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,wọn kò lè dúró;nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.

22. Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,bí àwọn tí wọn ń gé igi.

23. Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.

24. A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

25. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

26. N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Jeremaya 46