Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 37:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn.

8. Àwọn ará Kalidea sì ń pada bọ̀ wá gbé ogun ti ìlú yìí; wọn yóo gbà á, wọn yóo sì dáná sun ún.

9. OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ.

10. Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná.

11. Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀,

12. Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀.

13. Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.”

14. Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè.

Ka pipe ipin Jeremaya 37