Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 35:6-19 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae.

7. A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé.

8. A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin.

9. Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn.

10. Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́.

11. Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.”

12. OLUWA bá sọ fún Jeremaya pé,

13. “Èmi OLUWA, àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o lọ sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu pé, ṣé wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ kí wọn sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi ni?

14. Àwọn ọmọ Rekabu pa òfin tí Jonadabu, baba ńlá wọn, fún wọn mọ́, pé kí wọn má mu ọtí waini, wọn kò sì mu ọtí rárá títí di òní olónìí, nítorí pé wọ́n pa àṣẹ baba ńlá wọn mọ́. Mo ti bá yín sọ̀rọ̀ ní ọpọlọpọ ìgbà, ṣugbọn ẹ kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

15. Mo ti rán gbogbo àwọn iranṣẹ mi, àwọn wolii, si yín, ní ọpọlọpọ ìgbà pé kí olukuluku yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú tí ó ń tọ̀, kí ẹ tún ìwà yín ṣe, kí ẹ má sá tẹ̀lé àwọn oriṣa kiri, kí ẹ yé máa sìn wọ́n; kí ẹ lè máa gbé ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Ṣugbọn ẹ kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

16. Àwọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu mú àṣẹ baba ńlá wọn tí ó pa fún wọn ṣẹ, ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.

17. Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ́ kí ibi bá àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, nítorí pé mo bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kò gbọ́; mo pè wọ́n, wọn kò dáhùn.”

18. Ṣugbọn Jeremaya sọ fún àwọn ọmọ Rekabu pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘Nítorí pé ẹ gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá yín lẹ́nu, ẹ sì pa gbogbo òfin rẹ̀ mọ́, ẹ sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ pé kí ẹ máa ṣe,

19. nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní títí lae, kò ní sí ìgbà kan tí Jonadabu, ọmọ Rekabu kò ní ní ẹnìkan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú mi.’ ”

Ka pipe ipin Jeremaya 35