Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 35:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Jehoiakimu ọmọ Josaya, ọba Juda; ó ní,

2. “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu kí o bá wọn sọ̀rọ̀, mú wọn wá sinu ọ̀kan ninu àwọn yàrá tí ó wà ninu ilé OLUWA, kí o sì fi ọtí lọ̀ wọ́n.”

3. Mo bá mú Jaasanaya ọmọ Jeremaya ọmọ Habasinaya ati àwọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ati gbogbo ìdílé Rekabu,

4. mo mú wọn wá sinu ilé OLUWA. Mo kó wọn lọ sinu yàrá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hanani, ọmọ Igidalaya eniyan Ọlọrun, yàrá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yàrá àwọn ìjòyè, lókè yàrá Maaseaya ọmọ Ṣalumu, aṣọ́nà.

5. Mo gbé ìgò ọtí kalẹ̀ níwájú àwọn ọmọ Rekabu, mo kó ife tì í. Mo bá sọ fún wọn pé, “Ó yá, ẹ máa mu ọtí waini.”

6. Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “A kò ní mu ọtí kankan nítorí pé Jonadabu, baba ńlá wa tíí ṣe ọmọ Rekabu ti pàṣẹ fún wa pé a kò gbọdọ̀ mu ọtí, ati àwa ati arọmọdọmọ wa títí lae.

7. A kò gbọdọ̀ kọ́ ilé, a kò gbọdọ̀ dá oko, a kò gbọdọ̀ gbin ọgbà àjàrà. Ó ní inú àgọ́ ni kí á máa gbé ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, kí ọjọ́ wa baà lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí à ń gbé.

8. A gbọ́ràn sí Jonadabu baba ńlá wa lẹ́nu, à ń pa gbogbo àṣẹ tí ó pa fún wa mọ́, pé kí á má mu ọtí ní gbogbo ọjọ́ ayé wa, àwa, àwọn aya wa ati àwọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin.

9. Ó ní a kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tí a óo máa gbé. A kò ṣe ọgbà àjàrà, tabi kí á dá oko, tabi kí á gbin ohun ọ̀gbìn.

10. Inú àgọ́ ni à ń gbé, a sì pa gbogbo àṣẹ tí Jonadabu baba ńlá wa fún wa mọ́.

Ka pipe ipin Jeremaya 35