Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 3:9-25 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí pé ìwà àgbèrè jẹ́ nǹkan kékeré lójú rẹ̀, ó ṣe àgbèrè pẹlu òkúta ati igi ó sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.

10. Sibẹsibẹ, lẹ́yìn gbogbo èyí, Juda arabinrin rẹ̀, ọ̀dàlẹ̀, kò fi tọkàntọkàn pada tọ̀ mí wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ojú ayé ni wọ́n ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11. Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún mi pé, “Israẹli jẹ̀bi, aiṣootọ, ṣugbọn kò tíì tó ti Juda, ọ̀dàlẹ̀.

12. Lọ kéde ọ̀rọ̀ yìí sí ìhà àríwá, kí o wí pé:‘Yipada ìwọ Israẹli alaiṣootọ.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N kò ní bínú sí ọ, nítorí aláàánú ni mí.N kò ní máa bínú lọ títí lae.

13. Ṣá ti gbà pé o jẹ̀bi,ati pé o ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi OLUWA Ọlọrun rẹ.O ti fi ògo rẹ wọ́lẹ̀ fún àwọn àjèjì oriṣa,lábẹ́ gbogbo igi tútù;o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’

14. “Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ, nítorí èmi ni Oluwa yín. N óo yan ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu yín láti inú ìlú kọ̀ọ̀kan, n óo mú meji meji láti inú agbo ilé kọ̀ọ̀kan, n óo sì ko yín wá sí Sioni.

15. N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.

16. Nígbà tí ẹ bá pọ̀ síi ní ilẹ̀ náà, ẹ kò ní sọ̀rọ̀ nípa Àpótí Majẹmu OLUWA mọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sọ si yín lọ́kàn, ẹ kò ní ranti rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín kò ní fà sí i mọ́, ẹ kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀

17. Ìtẹ́ OLUWA ni wọ́n óo máa pe Jerusalẹmu nígbà náà. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo parapọ̀ wá sibẹ, níwájú èmi OLUWA, ní Jerusalẹmu, wọn kò ní fi oríkunkun tẹ̀ sí ìmọ̀ burúkú ọkàn wọn mọ́.

18. Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ará ilé Juda yóo tọ àwọn ará ilé Israẹli lọ, wọn yóo sì jọ pada láti ilẹ̀ ìhà àríwá, wọn yóo wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín tí wọ́n jogún.”

19. OLUWA ní,“Israẹli, mo fẹ́ fi ọ́ ṣe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi,tí n óo sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó dára,kí n sì fún ọ ní ogún tí ó dára jù,láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù.Mo sì rò pé o óo máa pè mí ní baba rẹ,ati pé o kò ní pada kúrò lẹ́yìn mi.

20. Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

21. A gbọ́ ohùn kan lórí àwọn òkè gíga,ẹkún ati ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọkunrin Israẹli ni.Nítorí wọ́n ti yapa kúrò lójú ọ̀nà wọn;wọ́n ti gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn.

22. Ẹ yipada, ẹ̀yin alaiṣootọ ọmọ,n óo mú aiṣootọ yín kúrò.“Wò wá! A wá sọ́dọ̀ rẹ,nítorí ìwọ ni OLUWA Ọlọrun wa.

23. Nítòótọ́, ẹ̀tàn ni àwọn òkè,ati gbogbo ohun tí wọn ń lọ ṣe níbẹ̀;dájúdájú lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wa ni ìgbàlà Israẹli wà.

24. Ṣugbọn láti ìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú yìíti pa gbogbo ohun tí àwọn baba ńlá wa ṣiṣẹ́ fún run:ẹran ọ̀sìn wọn, ati agbo mààlúù wọn,àwọn ọmọ wọn lọkunrin ati lobinrin.

25. Ẹ jẹ́ kí á dojúbolẹ̀ kí ìtìjú wa sì bò wá,nítorí pé a ti ṣẹ̀ sí OLUWA Ọlọrun wa;àtàwa, àtàwọn baba ńlá wa,a kò gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní.”

Ka pipe ipin Jeremaya 3