Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 16:17-21 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi.

18. N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.”

19. OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi,ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ,láti gbogbo òpin ayé,wọn yóo máa wí pé:“Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún,ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan.

20. Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun?Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.”

21. OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀;àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi;wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Jeremaya 16