Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta.