Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 15:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.”

5. OLUWA ní,“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?Ta ni yóo dárò yín?Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín?

6. Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,tí mo sì pa yín run.Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.

7. Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;mo ti pa àwọn eniyan mi run,nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.

8. Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

9. Ẹni tí ó bí ọmọ meje ṣe àárẹ̀, ó sì dákú,oòrùn rẹ̀ wọ̀ lọ́sàn-án gangan.Ìtìjú ati àbùkù bá a.N óo jẹ́ kí ọ̀tá fi idà pa àwọn tí wọ́n kù ninu wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

10. Mo gbé! Ìyá mi, kí ló dé tí o bí mi, èmi tí mo di oníjà ati alárìíyànjiyàn láàrin gbogbo ìlú! N kò yá ẹnikẹ́ni lówó, bẹ́ẹ̀ n kò yáwó lọ́wọ́ ẹnìkan, sibẹsibẹ gbogbo wọn ni wọ́n ń ṣépè lé mi.

11. Kí èpè wọn mọ́ mi, OLUWA, bí n kò bá sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere níwájú rẹ, bí n kò bá gbadura fún àwọn ọ̀tá mi ní àkókò ìyọnu ati ìdààmú wọn.

12. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè ṣẹ́ irin, pàápàá, irin ilẹ̀ àríwá tí wọn fi idẹ lú?

13. OLUWA bá dáhùn pé, “Nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, n óo fi ọrọ̀ ati ohun ìṣúra rẹ fún àwọn tí ń kó ìkógun ní gbogbo agbègbè rẹ, láìgba owó lọ́wọ́ wọn.

14. N óo mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò dé rí. Mo ti fi ibinu dá iná kan, ó ti ràn, yóo máa jó ọ, kò sì ní kú laelae.”

Ka pipe ipin Jeremaya 15