Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 15:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ!

2. Bí wọ́n bá bi ọ́ pé níbo ni kí àwọn ó lọ, sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní,‘Àwọn tí wọn yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn,kì àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo kú ikú ogun,kí ogun pa wọ́n.Àwọn tí wọn yóo kú ikú ìyàn,kí ìyàn pa wọ́n;àwọn tí wọn yóo lọ sí ìgbèkùn,kí ogun kó wọn lọ.’

3. Oríṣìí ìparun mẹrin ni n óo jẹ́ kí ó dé bá wọn: idà óo pa wọ́n, ajá óo fà wọ́n ya, àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko óo jẹ wọ́n ní àjẹrun.

4. N óo sọ wọ́n di ohun tí ó bani lẹ́rù fún gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé, nítorí ohun tí Manase, ọmọ Hesekaya, ọba Juda, ṣe ní Jerusalẹmu.”

5. OLUWA ní,“Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ta ni yóo ṣàánú yín?Ta ni yóo dárò yín?Ta ni yóo ya ọ̀dọ̀ yín, láti bèèrè alaafia yín?

6. Ẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀,ẹ sì ń pada lẹ́yìn mi; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí náà ni mo ṣe na ọwọ́ ibinu mi si yín,tí mo sì pa yín run.Mo ti mú sùúrù, ó ti sú mi.

7. Mo ti fẹ́ wọn bí ẹni fẹ́ ọkà ní ibi ìpakà,ní ẹnubodè ilẹ̀ náà.Mo ti kó ọ̀fọ̀ bá wọn;mo ti pa àwọn eniyan mi run,nítorí wọn kò yipada kúrò ní ọ̀nà wọn.

8. Mo ti mú kí opó pọ̀ láàrin wọn ju iyanrìn inú òkun lọ.Mo mú kí apanirun gbógun ti àwọn ìyá àwọn ọdọmọkunrin ní ọ̀sán gangan.Mo mú kí ìbẹ̀rù ati ìwárìrì já lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Jeremaya 15