Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 12:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Olódodo ni ọ́, OLUWA,nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́;sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ.Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?

2. O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò;wọ́n dàgbà, wọ́n so èso;orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn,ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ.

3. Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí,O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wòo mọ èrò mi sí ọ.Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa,yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun.

4. Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀,tí koríko oko yóo rọ?Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀,àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé,nítorí àwọn eniyan ń wí pé,“Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”

5. OLUWA ní,“Bí o bá àwọn tí ń fi ẹsẹ̀ sáré sáré, tí ó bá rẹ̀ ọ́,báwo ni o ṣe lè bá ẹṣin sáré?Bí o bá sì ń ṣubú ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú,báwo ni o óo ti ṣe nígbà tí o bá dé aṣálẹ̀ Jọdani?

6. Nítorí pé àwọn arakunrin rẹ pàápàáati àwọn ará ilé baba rẹti hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí ọ;àwọn gan-an ni wọ́n ń ṣe èké rẹ:Má gbẹ́kẹ̀lé wọn,bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rere sí ọ.”

7. OLUWA wí pé,“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Jeremaya 12