Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 11:9-19 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀.

10. Wọ́n ti pada sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n ti bá àwọn ọlọrun mìíràn lọ, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda ti da majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.

11. Nítorí náà, OLUWA ní, òun óo mú kí ibi ó dé bá wọn, ibi tí wọn kò ní lè bọ́ ninu rẹ̀. Ó ní bí wọ́n tilẹ̀ ké pe òun, òun kò ní fetí sí tiwọn.

12. Ó ní àwọn ìlú Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu yóo ké pe àwọn oriṣa tí wọn ń sun turari sí, ṣugbọn àwọn oriṣa kò ní lè gbà wọ́n lọ́jọ́ ìṣòro.

13. Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀.

14. “Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn.

15. “Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà?

16. Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná.

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”

18. OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19. Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

Ka pipe ipin Jeremaya 11