Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 11:14-19 BIBELI MIMỌ (BM)

14. “Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn.

15. “Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà?

16. Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná.

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”

18. OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19. Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

Ka pipe ipin Jeremaya 11