Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 50:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ̀ parí, Josẹfu sọ fún àwọn ará ilé Farao pé, “Ẹ jọ̀wọ́, bí inú yín bá dùn sí mi, ẹ bá mi sọ fún Farao pé,

5. baba mi mú mi búra nígbà tí àtikú rẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, pé, ‘Nígbà tí mo bá kú, ninu ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani, ni kí ẹ sin mí sí.’ Nítorí náà, kí Farao jọ̀wọ́, fún mi láàyè kí n lọ sin òkú baba mi, n óo sì tún pada wá.”

6. Farao dáhùn, ó ní, “Lọ sin òkú baba rẹ gẹ́gẹ́ bí o ti búra fún un.”

7. Josẹfu lọ sin òkú baba rẹ̀, gbogbo àwọn iranṣẹ Farao sì bá a lọ, ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà ààfin ọba, ati gbogbo àwọn àgbààgbà ìlú Ijipti,

8. ati gbogbo ìdílé Josẹfu àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀, àfi àwọn ọmọde, àwọn agbo ẹran, ati àwọn mààlúù nìkan ni ó kù sí ilẹ̀ Goṣeni.

9. Kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin bá a lọ pẹlu, àwọn eniyan náà pọ̀ lọpọlọpọ.

10. Nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Atadi, níwájú Jọdani, wọ́n pohùnréré ẹkún, Josẹfu sì ṣọ̀fọ̀ baba rẹ̀ fún ọjọ́ meje.

11. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.

12. Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn.

13. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú.

14. Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ.

15. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.”

16. Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé,

17. ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún.

18. Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 50