Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 50:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.

12. Àwọn ọmọ Jakọbu sin òkú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún wọn.

13. Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú.

14. Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ.

15. Nígbà tí àwọn arakunrin Josẹfu rí i pé baba àwọn ti kú, wọ́n ní, “Ó ṣeéṣe kí Josẹfu kórìíra wa, kí ó sì gbẹ̀san gbogbo ibi tí a ti ṣe sí i.”

16. Wọ́n bá ranṣẹ sí Josẹfu pé, “Baba rẹ ti fi àṣẹ yìí lélẹ̀ kí ó tó kú pé,

17. ‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún.

18. Àwọn arakunrin rẹ̀ náà sì wá, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ní, “Wò ó, a di ẹrú rẹ.”

19. Ṣugbọn Josẹfu wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, èmi kì í ṣe Ọlọrun.

20. Ní tiyín, ẹ gbèrò ibi sí mi, ṣugbọn Ọlọrun yí i pada sí rere, kí ó lè dá ẹ̀mí ọpọlọpọ eniyan tí wọ́n wà láàyè lónìí sí.

21. Nítorí náà, ẹ má bẹ̀rù, n óo máa tọ́jú ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sọ̀rọ̀ ìtùnú fún wọn, tí ó sì dá wọn lọ́kànle.

22. Josẹfu sì ń gbé ilẹ̀ Ijipti, òun ati ìdílé baba rẹ̀, ó gbé aadọfa (110) ọdún láyé.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 50