Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 44:15-31 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Josẹfu bi wọ́n léèrè, ó ní, “Irú kí ni ẹ dánwò yìí? Ó jọ bí ẹni pé ẹ kò lérò pé irú mi lè woṣẹ́ ni?”

16. Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.”

17. Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí á má rí i pé mo ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Ẹnìkan ṣoṣo tí wọ́n ká ife náà mọ́ lọ́wọ́ ni yóo di ẹrú mi, ní tiyín, ẹ máa pada tọ baba yín lọ ní alaafia.”

18. Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí.

19. Oluwa mi, ranti pé o bi àwa iranṣẹ rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹ ní baba tabi arakunrin mìíràn?’

20. A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’

21. O sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé kí á mú un tọ̀ ọ́ wá, kí o lè fi ojú rí i.

22. A sì sọ fún ọ pé, ‘Ọmọ náà kò lè fi baba rẹ̀ sílẹ̀, nítorí pé bí ó bá fi baba rẹ̀ sílẹ̀, baba rẹ̀ yóo kú.’

23. O bá sọ fún àwa iranṣẹ rẹ pé bí àbíkẹ́yìn wa patapata kò bá bá wa wá, a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ mọ́.

24. “Nígbà tí a pada dé ọ̀dọ̀ baba wa, iranṣẹ rẹ, a rò fún un bí o ti wí.

25. Nígbà tí ó ní kí á tún lọ ra oúnjẹ díẹ̀ wá,

26. a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá.

27. Baba wa sọ fún wa pé a mọ̀ pé ọkunrin meji ni Rakẹli, aya òun bí fún òun,

28. ọ̀kan fi òun sílẹ̀, òun sì wí pé, dájúdájú, ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, òun kò sì tíì fi ojú òun kàn án láti ìgbà náà.

29. Ó ní bí a bá tún mú eléyìí kúrò lọ́dọ̀ òun, bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí i, pẹlu arúgbó ara òun yìí, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo pa òun.

30. “Nítorí náà, bí mo bá pada dé ọ̀dọ̀ baba mi tí n kò sì mú ọmọdekunrin náà lọ́wọ́, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ọmọdekunrin yìí gan-an ni ó fi ẹ̀mí tẹ̀,

31. bí kò bá rí i pẹlu wa, kíkú ni yóo kú. Yóo sì wá jẹ́ pé àwa ni a fa ìbànújẹ́ fún baba wa, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ìbànújẹ́ yìí ni yóo sì pa á.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 44