Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 30:27-43 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi,

28. sọ iye tí o bá fẹ́ máa gbà, n óo sì máa san án fún ọ.”

29. Jakọbu bá dáhùn pé, “Ìwọ náà mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ ati bí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ ti ṣe dáradára lọ́wọ́ mi.

30. Ẹran ọ̀sìn díẹ̀ ni o ní kí n tó dé ọ̀dọ̀ rẹ, díẹ̀ náà ti di pupọ nisinsinyii OLUWA ti bukun ọ ní gbogbo ọ̀nà nítorí tèmi. Nígbà wo ni èmi gan-an yóo tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àkójọ àwọn ohun tí mo lè pè ní tèmi?”

31. Labani bá bi í léèrè pé, “Kí ni kí n máa fún ọ?” Jakọbu dáhùn pé, “Má fún mi ní ohunkohun, bí o bá gbà láti ṣe ohun kan fún mi, n óo tún máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ.

32. Jẹ́ kí n bọ́ sí ààrin àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ lónìí, kí n sì ṣa gbogbo ọmọ aguntan dúdú, ati gbogbo ọmọ ewúrẹ́ ati aguntan tí ó ní dúdú tóótòòtóó lára, tí ó dàbí adíkálà, irú àwọn ẹran wọnyi ni n óo máa gbà fún iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún ọ.

33. Bẹ́ẹ̀ ni òdodo mi yóo jẹ́rìí gbè mí ní ọjọ́ iwájú, nígbà tí o bá wá wo ọ̀yà mi. Èyíkéyìí tí kò bá jẹ́ dúdú ninu àwọn aguntan, tabi ewúrẹ́ tí àwọ̀ rẹ̀ kò bá ní dúdú tóótòòtóó tí o bá rí láàrin àwọn ẹran mi, a jẹ́ pé mo jí i gbé ni.”

34. Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, ohun tí o wí gan-an ni a óo ṣe.”

35. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.

36. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá kó wọn lọ jìnnà sí Jakọbu, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta. Jakọbu bá ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù.

37. Jakọbu gé ọ̀pá igi populari ati ti alimọndi, ati ti pilani tútù, ó bó àwọn ọ̀pá náà ní àbófín, ó jẹ́ kí funfun wọn hàn síta.

38. Ó to àwọn ọ̀pá wọnyi siwaju àwọn ẹran níbi tí wọ́n ti ń mu omi, nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá wá mu omi ni wọ́n máa ń gùn.

39. Àwọn ẹran náà ń gun ara wọn níwájú àwọn ọ̀pá wọnyi, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà ati àwọn tí wọ́n ní funfun tóótòòtóó.

40. Jakọbu ṣa àwọn ọmọ aguntan wọnyi sọ́tọ̀, ó sì tún mú kí gbogbo agbo ẹran Labani dojú kọ àwọn ẹran tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó tabi tí ó dàbí adíkálà, tabi àwọn tí wọ́n jẹ́ dúdú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa àwọn ẹran tirẹ̀ sinu agbo kan lọ́tọ̀, kò pa wọ́n pọ̀ pẹlu ti Labani.

41. Nígbà tí àwọn ẹran tí ara wọ́n le dáradára láàrin agbo bá ń gùn, Jakọbu a fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, kí wọ́n lè máa gùn láàrin wọn.

42. Ṣugbọn nígbà tí àwọn ẹran tí kò lókun ninu tóbẹ́ẹ̀ bá ń gùn, kì í fi àwọn ọ̀pá náà siwaju wọn, báyìí ni àwọn ẹran tí kò lókun ninu di ti Labani, àwọn tí wọ́n lókun ninu sì di ti Jakọbu.

43. Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu ṣe di ọlọ́rọ̀ gidigidi, ó sì ní àwọn agbo ẹran ńláńlá, ọpọlọpọ iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin, ràkúnmí ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 30