Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 11:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á sọ̀kalẹ̀ lọ bá wọn, kí á dà wọ́n ní èdè rú, kí wọn má baà gbọ́ èdè ara wọn mọ́.”

8. Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe fọ́n wọn káàkiri sí gbogbo orílẹ̀ ayé, wọ́n pa ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó tì.

9. Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé.

10. Àkọsílẹ̀ ìran Ṣemu nìyí: ọdún keji lẹ́yìn tí ìkún omi ṣẹlẹ̀, tí Ṣemu di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ni ó bí Apakiṣadi.

11. Lẹ́yìn tí Ṣemu bí Apakiṣadi tán, ó tún gbé ẹẹdẹgbẹta (500) ọdún sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

12. Nígbà tí Apakiṣadi di ẹni ọdún marundinlogoji ni ó bí Ṣela.

13. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

14. Nígbà tí Ṣela di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.

15. Ó tún gbé ọdún mẹtalenirinwo (403) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

16. Nígbà tí Eberi di ẹni ọdún mẹrinlelọgbọn ni ó bí Pelegi.

17. Eberi tún gbé ojilenirinwo ó dín mẹ́wàá (430) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Pelegi tán, ó tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 11