Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 1:18-31 BIBELI MIMỌ (BM)

18. láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

19. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin.

20. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ.

21. Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

22. Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.”

23. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un.

24. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

25. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

26. Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.”

27. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.

28. Ó súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo ayé. Kí ayé wà ní ìkáwọ́ yín, kí ẹ ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú omi, lórí ẹyẹ ojú ọ̀run, ati lórí gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé.”

29. Ọlọrun tún wí pé, “Mo ti pèsè gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ń so èso ati igi tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu fún yín láti jẹ.

30. Bẹ́ẹ̀ ni mo sì ti pèsè àwọn ewéko fún oúnjẹ àwọn ẹranko, ati àwọn ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, ati gbogbo ẹ̀dá alààyè.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

31. Ọlọrun wo gbogbo ohun tí ó dá, ó sì rí i pé wọ́n dára. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹfa.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 1