Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 1:14-27 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn,

15. kí wọ́n sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ní ojú ọ̀run láti máa tàn sórí ilẹ̀ ayé, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

16. Ọlọrun dá ìmọ́lẹ̀ ńlá meji: ó dá oòrùn láti máa jọba ọ̀sán, ati òṣùpá láti máa jọba òru, ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹlu.

17. Ọlọrun fi wọ́n sí ojú ọ̀run láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé,

18. láti máa jọba lórí ọ̀sán ati òru, ati láti fi ààlà sí ààrin ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

19. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ kẹrin.

20. Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi kún fún oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè, kí ojú ọ̀run sì kún fún àwọn ẹyẹ.

21. Ó dá àwọn ẹranko ńláńlá inú omi ati oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

22. Ọlọrun súre fún wọn, ó ní, “Ẹ máa bímọ lémọ, kí ẹ sì máa pọ̀ sí i, kí ẹ kún gbogbo inú omi òkun, kí àwọn ẹyẹ náà sì máa pọ̀ sí i lórí ilẹ̀.”

23. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ karun-un.

24. Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ mú oríṣìíríṣìí ẹ̀dá alààyè jáde: oríṣìíríṣìí ẹran ọ̀sìn, oríṣìíríṣìí ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀ ati oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́, ó sì rí bẹ́ẹ̀.

25. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá gbogbo wọn, ó wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.

26. Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á dá eniyan ní àwòrán ara wa, kí ó rí bíi wa, kí wọ́n ní àṣẹ lórí àwọn ẹja inú òkun, ẹyẹ ojú ọ̀run, àwọn ẹranko ati lórí gbogbo ayé ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà lórí ilẹ̀.”

27. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun dá eniyan ní àwòrán ara rẹ̀. Takọ-tabo ni ó dá wọn.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 1