Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 2:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà náà ni mo sọ lọ́kàn ara mi pé, “Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ni yóo ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Kí wá ni ìwúlò ọgbọ́n mi?” Mo sọ fún ara mi pé, asán ni eléyìí pẹlu.

16. Nítorí pé àtọlọ́gbọ́n, àtòmùgọ̀, kò sẹ́ni tíí ranti wọn pẹ́ lọ títí. Nítorí pé ní ọjọ́ iwájú, gbogbo wọn yóo di ẹni ìgbàgbé patapata. Ẹ wo bí ọlọ́gbọ́n ti í kú bí òmùgọ̀.

17. Nítorí náà mo kórìíra ayé, nítorí gbogbo nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ láyé ń bà mí ninu jẹ́, nítorí pé asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo wọn.

18. Mo kórìíra làálàá tí mo ti ṣe láyé, nígbà tí mo rí i pé n óo fi í sílẹ̀ fún ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi.

19. Ta ni ó sì mọ̀ bóyá ọlọ́gbọ́n ni yóo jẹ́, tabi òmùgọ̀ eniyan? Sibẹsibẹ òun ni yóo jọ̀gá lórí gbogbo ohun tí mo fi ọgbọ́n mi kó jọ láyé yìí. Asán ni èyí pẹlu.

20. Nítorí náà mo pada kábàámọ̀ lórí gbogbo ohun tí mo fi làálàá kójọ.

21. Nítorí pé nígbà mìíràn ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹlu ọgbọ́n, ìmọ̀ ati òye yóo fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣe làálàá fún wọn. Asán ni èyí pẹlu, nǹkan burúkú sì ni.

22. Kí ni eniyan rí gbà ninu gbogbo làálàá rẹ̀, kí sì ni èrè eniyan lórí akitiyan, ati iṣẹ́ tí ó ń ṣe láyé.

23. Nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ kún fún ìrora, iṣẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ìbànújẹ́ fún un. Ọkàn rẹ̀ kì í balẹ̀ lóru, asán ni èyí pẹlu.

24. Kò sí ohun tí ó dára fún eniyan ju kí ó jẹun kí ó sì máa gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Sibẹ mo rí i pé ọwọ́ Ọlọrun ni èyí tún ti ń wá.

25. Nítorí láìsí àṣẹ rẹ̀, ta ló lè jẹun, tabi kí ó gbádùn ohunkohun.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 2