Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Oníwàásù 1:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Inú òkun ni gbogbo odò tí ń ṣàn ń lọ, ṣugbọn òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ń ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n tún ṣàn pada lọ.

8. Gbogbo nǹkan ní ń kó àárẹ̀ bá eniyan, ju bí ẹnu ti lè sọ lọ. Ìran kì í sú ojú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ kì í kún etí.

9. Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóo máa wà. Ohun tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ náà ni a óo tún máa ṣe, kò sí ohun titun kan ní ilé ayé.

10. Ǹjẹ́ ohun kankan wà tí a lè tọ́ka sí pé: “Wò ó! Ohun titun nìyí.” Ó ti wà rí ní ìgbà àtijọ́.

11. Kò sí ẹni tí ó ranti àwọn nǹkan àtijọ́ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni, kò sì ní sí ẹni tí yóo ranti àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.

12. Èmi ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti jẹ ọba lórí Israẹli, ní Jerusalẹmu.

13. Mo fi tọkàntọkàn pinnu láti fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe láyé.Làálàá lásán ni iṣẹ́ tí Ọlọrun fún ọmọ eniyan ṣe lórí ilẹ̀ ayé.

14. Mo ti wo gbogbo nǹkan tí eniyan ń ṣe láyé, wò ó, asán ati ìmúlẹ̀mófo ni gbogbo rẹ̀.

15. Ohun tí ó bá ti wọ́, ẹnìkan kò lè tọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè ka ohun tí kò bá sí.

16. Mo wí lọ́kàn ara mi pé, “Mo ti kọ́ ọpọlọpọ ọgbọ́n, ju gbogbo àwọn tí wọ́n ti jọba ní Jerusalẹmu ṣáájú mi lọ. Mo ní ọpọlọpọ ìrírí tí ó kún fún ọgbọ́n ati ìmọ̀.”

17. Mo pinnu lọ́kàn mi láti mọ ohun tí ọgbọ́n jẹ́, ati láti mọ ohun tí ìwà wèrè ati ìwà òmùgọ̀ jẹ́. Mo wá wòye pé èyí pàápàá jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

18. Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.

Ka pipe ipin Ìwé Oníwàásù 1