Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 8:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀.

2. Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán.

3. Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí.

4. Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì.

5. Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ.

6. OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.”

7. OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri.

8. Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan!

9. Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.”

10. Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká.

Ka pipe ipin Isikiẹli 8