Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 45:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.

2. Ẹ óo fi ààyè sílẹ̀ ninu ilẹ̀ yìí fún Tẹmpili mímọ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ, ẹ óo sì tún fi aadọta igbọnwọ ilẹ̀ sílẹ̀ yí i ká.

3. Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo wọn apá kan tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10), níbẹ̀ ni ilé mímọ́ yóo wà, yóo jẹ́ ibi mímọ́ jùlọ.

4. Yóo jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà, yóo wà fún àwọn alufaa, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, tí wọ́n sì ń dúró níwájú OLUWA láti ṣe iṣẹ́ iranṣẹ. Ibẹ̀ ni wọn yóo kọ́ ilé wọn sí, ibẹ̀ ni yóo sì jẹ́ ilẹ̀ mímọ́ fún ibi mímọ́ mi.

5. Ẹ wọn ibòmíràn tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 10). Ibẹ̀ ni yóo wà fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili, ibẹ̀ ni wọn óo máa gbé.

6. “Lára ilẹ̀ mímọ́ náà, ẹ óo ya apá kan sọ́tọ̀ tí òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), tí ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), ilẹ̀ yìí yóo wà fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

7. “Ọba ni yóo ni ilẹ̀ tí ó yí ilẹ̀ mímọ́ náà ká nì ẹ̀gbẹ́ kinni keji, ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ninu ìlú náà, ní ìwọ̀ oòrùn ati ìlà oòrùn, yóo gùn tó ilẹ̀ ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli, yóo bẹ̀rẹ̀ ní òpin ìwọ̀ oòrùn yóo sì dé òpin ìlà oòrùn ilẹ̀ náà.

8. Yóo jẹ́ ìpín ti ọba ní Israẹli. Àwọn ọba kò gbọdọ̀ ni àwọn eniyan mi lára mọ́, wọ́n gbọdọ̀ fi ilẹ̀ yòókù sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.”

9. OLUWA Ọlọrun ní, “Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ̀yin ọba Israẹli, ẹ má hùwà ipá ati ìninilára mọ́, ẹ máa hùwà ẹ̀tọ́ ati òdodo, ẹ má lé àwọn eniyan mi jáde mọ́.

10. “Òṣùnwọ̀n eefa ati ti bati tí ó péye ni kí ẹ máa lò.

11. “Òṣùnwọ̀n eefa ati òṣùnwọ̀n bati náà gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà, eefa ati bati yín gbọdọ̀ jẹ́ ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n homeri kan. Òṣùnwọ̀n homeri ni ó gbọdọ̀ jẹ́ òṣùnwọ̀n tí ẹ óo máa fi ṣiṣẹ́.

12. “Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli.

13. “Ohun tí ẹ óo máa fi rúbọ sí OLUWA nìwọ̀nyí: ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri ọkà yín kọ̀ọ̀kan, ati ìdámẹ́fà òṣùnwọ̀n eefa kan ninu òṣùnwọ̀n homeri alikama yín kọ̀ọ̀kan.

Ka pipe ipin Isikiẹli 45