“Nígbà tí ẹ bá pín ilẹ̀ náà fún àwọn eniyan, ẹ ya ilẹ̀ kan sọ́tọ̀ fún OLUWA, tí yóo jẹ́ ilẹ̀ mímọ́. Gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000) igbọnwọ. Ilẹ̀ mímọ́ ni gbogbo ilẹ̀ náà yóo jẹ́.