Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 42:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà ó mú mi jáde, ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn ti inú lápá ìhà àríwá, ó sì mú mi wọ inú àwọn yàrá tí ó wà níwájú àgbàlá Tẹmpili, ati níwájú ilé tí ó wà ní ìhà àríwá.

2. Òòró ilé tí ó wà ní ìhà àríwá náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25).

3. Ibùjókòó-òkè meji tí ó kọjú sí ara wọn wà ní àgbékà mẹtẹẹta; wọ́n wà lára ògiri láti nǹkan bíi ogún igbọnwọ sí ara gbọ̀ngàn inú, ati ibi tí ó kọjú sí pèpéle tí ó wà lára gbọ̀ngàn òde.

4. Ọ̀nà kan wà níwájú àwọn yàrá tí ó lọ sinu, ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ó sì gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ní ìhà àríwá.

5. Àwọn yàrá ti àgbékà kẹta kéré, nítorí ibùjókòó-òkè ti àgbékà kẹta fẹ̀ ju àwọn tí wọ́n wà níwájú àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti àgbékà ààrin lọ.

Ka pipe ipin Isikiẹli 42