Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 32:19-31 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Sọ fún wọn pé,‘Ta ni ó lẹ́wà jùlọ?Sùn kalẹ̀, kí á sì tẹ́ ọ sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.’

20. “Wọn yóo ṣubú láàrin àwọn tí wọ́n kú ikú ogun; ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ yóo ṣubú pẹlu rẹ̀.

21. Àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ akọni ati àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn yóo máa sọ nípa wọn ninu isà òkú pé, ‘Àwọn aláìkọlà tí a fi idà pa ti ṣubú, wọ́n ti wọlẹ̀, wọ́n sùn, wọn kò lè mira.’

22. “Asiria náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ibojì àwọn tí wọ́n ti kú yí i ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.

23. Ibojì rẹ̀ wà ní ìpẹ̀kun isà òkú. Ibojì àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì tò yí tirẹ̀ ká. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láyé, gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun.

24. “Elamu náà wà níbẹ̀, pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká. Gbogbo wọn ni wọ́n ti kú ikú ogun. Wọ́n sì lọ sinu isà òkú ní àìkọlà abẹ́. Àwọn tí ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè, wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀, wọn lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú.

25. Wọ́n tẹ́ ibùsùn fún Elamu láàrin àwọn tí wọ́n kú sójú ogun pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀. Ibojì wọn yí tirẹ̀ ká, gbogbo wọn ni a fi idà pa láìkọlà abẹ́. Wọ́n ń dẹ́rù ba àwọn eniyan nígbà tí wọ́n wà láàyè. Wọ́n fi ìtìjú wọlẹ̀ lọ, wọ́n lọ bá àwọn tí wọ́n wà ní ipò òkú. A kó gbogbo wọn pọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n kú sójú ogun.

26. “Meṣeki ati Tubali wà níbẹ̀ pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan wọn. Ibojì wọn yí ibojì rẹ̀ ká, gbogbo wọn ni wọ́n kú lójú ogun ní aláìkọlà. Nítorí wọ́n ń dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.

27. Wọn kò sin wọ́n bí àwọn alágbára tí wọ́n wà ní àtijọ́ tí wọ́n sin sí ibojì pẹlu ohun ìjà ogun wọn lára wọn: àwọn tí a gbé orí wọn lé idà wọn, wọ́n sì fi asà wọn bo egungun wọn mọ́lẹ̀; nítorí àwọn alágbára wọnyi dẹ́rù bani nígbà tí wọ́n wà láàyè.

28. “Nítorí náà, a óo wó ọ mọ́lẹ̀, o óo sì sùn láàrin àwọn aláìkọlà pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun.

29. “Edomu náà wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀. Bí wọ́n ti lágbára tó, wọ́n sùn pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Wọ́n sùn pẹlu àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.

30. “Gbogbo àwọn olórí láti apá àríwá wà níbẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Sidoni, tí wọ́n fi ìtìjú wọlé lọ sí ipò òkú pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lo agbára wọn láti dẹ́rù bani, wọ́n sùn láìkọlà, pẹlu ìtìjú, pẹlu àwọn tí wọ́n kú lójú ogun. Pẹlu àwọn tí wọ́n lọ sinu isà òkú.

31. “Nígbà tí Farao bá rí wọn, Tòun ti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a fi idà pa, yóo dá ara rẹ̀ lọ́kàn le, nítorí gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ka pipe ipin Isikiẹli 32