Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 30:22-26 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Nítorí náà, mo lòdì sí Farao, ọba Ijipti. Èmi OLUWA Ọlọrun ní mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo ṣẹ́ ẹ ní apá mejeeji: ati èyí tó ṣì lágbára, ati èyí tí ó ti ṣẹ́ tẹ́lẹ̀; n óo sì gbọn idà bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

23. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká orílẹ̀-èdè ayé, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé.

24. N óo fún ọba Babiloni lágbára, n óo sì fi idà mi lé e lọ́wọ́; ṣugbọn n óo ṣẹ́ Farao lápá; yóo máa kérora níwájú rẹ̀ bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́ tí ó ń kú lọ.

25. N óo fún ọba Babiloni lágbára, ṣugbọn ọwọ́ Farao yóo rọ. Wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Nígbà tí mo bá fi idà mi lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo fa idà náà yọ yóo gbógun ti ilẹ̀ Ijipti.

26. N óo fọ́n àwọn ará Ijipti ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo sì tú wọn káàkiri gbogbo ilẹ̀ ayé. Wọn óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 30