Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 28:16-26 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ninu ọpọlọpọ òwò tí ó ń ṣe, o bẹ̀rẹ̀ sí hu ìwà jàgídíjàgan, o sì dẹ́ṣẹ̀, nítorí náà mo lé ọ jáde bí ohun ìríra kúrò lórí òkè Ọlọrun. Kerubu tí ń ṣọ́ ọ sì lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn òkúta olówó iyebíye tí ń tàn yinrinyinrin.

17. Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.

18. O ti fi ọpọlọpọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí o dá nítorí ìwà aiṣootọ ninu òwò rẹ, ba ibi mímọ́ mi jẹ́. Nítorí náà, mo jẹ́ kí iná ṣẹ́ ní ààrin rẹ; ó sì jó ọ run; mo sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ ayé lójú gbogbo àwọn tí ń wò ọ́.

19. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́ láàrin àwọn eniyan láyé ni ó yà lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí ọ. Òpin burúkú ti dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́ títí ayé.’ ”

20. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

21. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú rẹ sí Sidoni, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ pé

22. OLUWA Ọlọrun ní, ‘Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni. N óo sì fi ògo mi hàn láàrin rẹ. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé inú rẹ; tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn wọ́n.

23. Nítorí n óo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá ọ jà n óo sì jẹ́ kí àgbàrá ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ní ìgboro rẹ. Àwọn tí wọ́n yí ọ ká yóo gbógun tì ọ́, wọn óo sì fi idà pa ọpọlọpọ eniyan ninu rẹ,’ nígbà náà o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

24. OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ti ilé Israẹli, kò ní sí ọ̀tá tí yóo máa ṣe ẹ̀gún gún wọn mọ́, láàrin gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká tí wọ́n sì ń kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.

25. “Nígbà tí mo bá kó àwọn ará ilé Israẹli jọ kúrò láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, tí mo sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrin wọn, lójú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, wọn óo máa gbé ilẹ̀ tiwọn, ilẹ̀ tí mo fún Jakọbu iranṣẹ mi.

26. Wọn óo máa gbé ibẹ̀ láìbẹ̀rù; wọn óo kọ́ ilé, wọn óo sì ṣe ọgbà àjàrà, wọn óo máa gbé láìbẹ̀rù nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n yí wọn ká, tí wọ́n sì ti kẹ́gàn wọn. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 28