Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 26:7-21 BIBELI MIMỌ (BM)

7. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.

8. Yóo fi idà pa àwọn ará ìlú kéékèèké tí ó wà ní agbègbè tí ó yí ọ ká. Wọn óo mọ òkítì sí ara odi rẹ, wọn yóo ru erùpẹ̀ jọ, wọn óo fi la ọ̀nà lẹ́yìn odi rẹ, wọn óo sì fi asà borí nígbà tí wọ́n bá ń gun orí odi rẹ bọ̀.

9. Wọn óo fi ìtì igi wó odi rẹ, wọn óo sì fi àáké wó ilé-ìṣọ́ rẹ lulẹ̀.

10. Ẹṣin rẹ̀ óo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí eruku ẹsẹ̀ wọn yóo bò ọ́ mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ati ti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù ati ti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ yóo mi odi rẹ tìtì, nígbà tí wọ́n bá dé ẹnubodè rẹ, bí ìgbà tí àwọn ọmọ ogun bá wọ ìlú tí odi rẹ̀ ti wó.

11. Yóo fi pátákò ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin rẹ̀ tú gbogbo ilẹ̀ ìgboro rẹ, yóo fi idà pa àwọn eniyan rẹ; yóo sì wó àwọn òpó ńláńlá rẹ lulẹ̀.

12. Yóo kó ọrọ̀ rẹ ati àwọn ọjà tí ò ń tà ní ìkógun. Yóo wó odi rẹ ati àwọn ilé dáradára tí ó wà ninu rẹ lulẹ̀. Yóo ru òkúta, ati igi, ati erùpẹ̀ tí ó wà ninu ìlú rẹ dà sinu òkun.

13. N óo wá fi òpin sí orin kíkọ ninu rẹ; a kò sì ní gbọ́ ohùn dùùrù ninu rẹ mọ́.

14. N óo sì sọ ọ́ di àpáta lásán, o óo di ibi tí wọn óo máa sá àwọ̀n sí; ẹnikẹ́ni kò sì ní tún ọ kọ́ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

15. OLUWA Ọlọrun sọ fún ìlú Tire pé, “Ǹjẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí ó wà létí òkun kò ní mì tìtì nítorí ìṣubú rẹ, nígbà tí àwọn tí wọ́n farapa bá ń kérora, tí a sì pa ọpọlọpọ ní ìpakúpa ninu rẹ?

16. Gbogbo àwọn ọba ìlú etí òkun yóo sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ wọn, wọn óo bọ́ aṣọ ìgúnwà wọn, ati agbádá ọlọ́nà tí wọ́n wọ̀, jìnnìjìnnì óo dà bò wọ́n, wọn óo jókòó sórí ilẹ̀, wọn óo bẹ̀rẹ̀ sí máa gbọ̀n, ẹnu óo sì yà wọ́n nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ.

17. Wọn yóo wá dá orin arò fún ọ pé:Wò ó bí o ti parẹ́ ninu òkun,ìwọ ìlú olókìkí,ìwọ ìlú tí ó lágbára lórí òkun,ìwọ ati àwọn tí ń gbé inú rẹ,àwọn tí wọn ń mú kí ẹ̀rù rẹ máa ba àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀.

18. Àwọn erékùṣù yóo wárìrì ní ọjọ́ ìṣubú rẹ.Nítòótọ́, àwọn erékùṣù tí wọ́n wà ninu òkun yóo dààmú nítorí ìparun rẹ.”

19. OLUWA Ọlọrun ní, “Nígbà tí mo bá sọ ọ́ di ìlú ìparun bí àwọn ìlú tí ẹnìkan kò gbé inú rẹ̀, nígbà tí mo bá mú kí omi òkun bò ọ́ mọ́lẹ̀, tí ibú omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀,

20. n óo fà ọ́ lulẹ̀ lọ bá àwọn ẹni àtijọ́ tí wọ́n wà ninu ọ̀gbun. N óo mú kí o máa gbé ìsàlẹ̀ ilẹ̀ bí ìlú àwọn tí wọ́n ti ṣègbé nígbà àtijọ́, ati àwọn tí wọ́n ti lọ sinu ọ̀gbun; kí ẹnikẹ́ni má baà gbé inú rẹ mọ́, kí o má sì sí lórí ilẹ̀ alààyè mọ́.

21. N óo mú òpin tí ó bani lẹ́rù dé bá ọ, o kò sì ní sí mọ́; bí ẹnikẹ́ni tilẹ̀ ń wá ọ, ẹnìkan kò ní rí ọ mọ́ títí lae. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 26