OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! N óo mú Nebukadinesari, ọba ńlá Babiloni wá, láti ìhà àríwá, yóo wá gbógun ti Tire. Nebukadinesari, ọba àwọn ọba óo wá, pẹlu ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọmọ ogun.