Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 23:39-49 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Ní ọjọ́ náà gan-an tí wọ́n pa àwọn ọmọ wọn, tí wọ́n fi wọ́n rúbọ sí oriṣa wọn, ni wọ́n tún wá sí ilé ìsìn mi, tí wọ́n sọ ọ́ di eléèérí. Wò ó! Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ní ilé mi.

40. “Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́.

41. Ẹ jókòó lórí àga ọlọ́lá. Ẹ tẹ́ tabili siwaju; ẹ wá gbé turari ati òróró mi lé e lórí.

42. Ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìbìkítà ẹ̀dá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo lọ́dọ̀ yín, àwọn ọkunrin ọ̀mùtí lásánlàsàn kan sì wá láti inú aṣálẹ̀, wọ́n kó ẹ̀gbà sí àwọn obinrin lọ́wọ́, wọ́n fi adé tí ó lẹ́wà dé wọn lórí.

43. Nígbà náà ni mo wí lọ́kàn ara mi pé, Ǹjẹ́ àwọn ọkunrin wọnyi kò tún ń ṣe àgbèrè, pẹlu àwọn obinrin panṣaga burúkú yìí?

44. Nítorí wọ́n ti tọ̀ wọ́n lọ bí àwọn ọkunrin tí ń tọ aṣẹ́wó lọ. Wọ́n wọlé tọ Ohola ati Oholiba lọ, wọ́n sì bá wọn ṣe àgbèrè.

45. Ṣugbọn àwọn olódodo eniyan ni yóo dá àwọn obinrin náà lẹ́jọ́ panṣaga, ati ti apànìyàn, nítorí pé panṣaga eniyan ni wọ́n, wọ́n sì ti paniyan.”

46. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ pe ogunlọ́gọ̀ eniyan lé wọn lórí kí wọ́n ṣẹ̀rù bà wọ́n, kí wọ́n sì kó wọn lẹ́rù;

47. kí ogunlọ́gọ̀ eniyan wọnyi óo sọ wọ́n lókùúta, wọn óo sì gún wọn ní idà. Wọn óo pa àwọn ọmọ wọn; tọkunrin tobinrin, wọn óo sì dáná sun ilé wọn.

48. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ní ilẹ̀ náà; èyí óo sì kọ́ gbogbo àwọn obinrin lẹ́kọ̀ọ́, pé kí wọ́n má máa ṣe ìṣekúṣe bíi tiyín.

49. N óo da èrè ìṣekúṣe yín le yín lórí, ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà yín. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 23