Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 23:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà:

23. àwọn ará Babiloni ati gbogbo àwọn ará Kalidea láti Pekodi, ati Ṣoa ati Koa, pẹlu gbogbo àwọn ará Asiria: àwọn ọdọmọkunrin tí ojú wọn fanimọ́ra, àwọn gomina, ati àwọn ọ̀gágun, tí gbogbo wọn jẹ́ olórí ogun, tí wọ́n sì ń gun ẹṣin.

24. Wọn óo dojú kọ ọ́ láti ìhà àríwá, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun, kẹ̀kẹ́ ẹrù, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọn óo gbógun tì ọ́ ní gbogbo ọ̀nà pẹlu apata, asà ati àkẹtẹ̀ ogun. N óo fi ìdájọ́ rẹ lé wọn lọ́wọ́, òfin ilẹ̀ wọn ni wọn óo sì tẹ̀lé tí wọn óo fi dá ọ lẹ́jọ́.

25. N óo dojú kọ ọ́ pẹlu ibinu, n óo jẹ́ kí wọ́n fi ìrúnú bá ọ jà. Wọn óo gé ọ ní etí ati imú, wọn óo sì fi idà pa àwọn eniyan rẹ tí wọ́n kù. Wọn óo kó àwọn ọmọ rẹ ọkunrin ati obinrin lọ, wọn óo sì dáná sun àwọn tí wọ́n kù.

26. Wọn yóo bọ́ aṣọ lára rẹ; wọn yóo kó gbogbo nǹkan ọ̀ṣọ́ rẹ lọ.

27. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí ìṣekúṣe ati àgbèrè tí o kó ti ilẹ̀ Ijipti wá. O kò ní ṣíjú wo àwọn ará Ijipti mọ́, o kò sì ní ranti wọn mọ́.”

28. OLUWA ní, “Mo ṣetán tí n óo fi ọ́ lé àwọn tí o kórìíra lọ́wọ́, àwọn tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

29. Ìkórìíra ni wọn yóo fi máa bá ọ gbé, wọn yóo kó gbogbo èrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ lọ, wọn yóo sì fi ọ́ sílẹ̀ ní ìhòòhò goloto. Wọn yóo tú ọ sí ìhòòhò, gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé aṣẹ́wó ni ọ́. Ìṣekúṣe ati àgbèrè rẹ ni

30. ó mú èyí wá sórí rẹ, nítorí o ti bá àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe àgbèrè, o sì ti fi oriṣa wọn ba ara rẹ jẹ́.

Ka pipe ipin Isikiẹli 23