Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 19:9-14 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọ́n sọ ìwọ̀ sí i nímú,wọ́n gbé e jù sinu àhámọ́,wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babiloni.Wọ́n fi sí àtìmọ́lé,kí wọ́n má baà gbọ́ ohùn rẹ̀ mọ́ lórí àwọn òkè Israẹli.

10. Ìyá rẹ dàbí àjàrà inú ọgbàtí a gbìn sí ẹ̀gbẹ́ odò;ó rúwé, ó yọ ẹ̀ka,nítorí ó rí omi lọpọlọpọ.

11. Ẹ̀ka rẹ̀ tí ó lágbárani a fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún àwọn olórí.Ó dàgbà, ó ga fíofío, láàrin àwọn igi igbó.Ó rí i bí ó ti ga, tí ẹ̀ka rẹ̀ sì pọ̀.

12. Ṣugbọn a fa àjàrà náà tu pẹlu ibinu,a sì jù ú sílẹ̀.Afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn mú kí ó gbẹ,gbogbo èso rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Igi rẹ̀ tí ó lágbára gbẹ, iná sì jó o.

13. Nisinsinyii, a ti tún un gbìn sinu aṣálẹ̀,ninu ilẹ̀ gbígbẹ níbi tí kò sí omi.

14. Iná ṣẹ́ lára igi rẹ̀,ó sì jó gbogbo ẹ̀ka ati èso rẹ̀.Kò sì ní igi tí ó lágbára mọ́,tí a lè fi gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ọba.Dájúdájú ọ̀rọ̀ arò ni ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti di orin arò.

Ka pipe ipin Isikiẹli 19