Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hagai 2:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kọkanlelogun oṣù keje, ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA tún sọ fún wolii Hagai, pé:

2. “Tún lọ sọ́dọ̀ Serubabeli ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù, kí o bèèrè pé,

3. ‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín?

4. Ṣugbọn, mú ọkàn le, ìwọ Serubabeli, má sì fòyà, ìwọ Joṣua, ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa; ẹ ṣe ara gírí kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ náà ẹ̀yin eniyan; nítorí mo wà pẹlu yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.

5. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí mo ṣe fun yín, nígbà tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, mo wà láàrin yín; nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù.’

6. “Nítorí pé èmi, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ ọ́ pé láìpẹ́, n óo tún mi ọ̀run ati ayé jìgìjìgì lẹ́ẹ̀kan sí i, ati òkun ati ilẹ̀.

7. N óo mi gbogbo orílẹ̀-èdè, wọn óo kó ìṣúra wọn wá, n óo sì ṣe ilé yìí lọ́ṣọ̀ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.

8. Tèmi ni gbogbo fadaka ati wúrà tí ó wà láyé; èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. Ògo tí ilé yìí yóo ní tó bá yá, yóo ju ti àtijọ́ lọ. N óo fún àwọn eniyan mi ní alaafia ati ibukun ninu rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”

10. Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kẹsan-an, ní ọdún keji ìjọba Dariusi, OLUWA sọ fún wolii Hagai pé,

11. “Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo ní kí o lọ bèèrè ìdáhùn lórí ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa.

12. Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.”

13. Nígbà náà ni Hagai tún bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá di aláìmọ́ nítorí pé ó farakan òkú, tí ó sì fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun tí a kà sílẹ̀ wọnyi ǹjẹ́ kò ní di aláìmọ́?” Wọ́n dáhùn pé: “Dájúdájú, yóo di aláìmọ́.”

14. Hagai bá dáhùn, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó rí fún àwọn eniyan wọnyi ati fún orílẹ̀-èdè yìí pẹlu iṣẹ́ ọwọ́ wọn níwájú OLUWA; gbogbo ohun tí wọ́n fi ń rúbọ jẹ́ aláìmọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA wí.

Ka pipe ipin Hagai 2