Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 2:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nígbà tí wundia kan bá ń lọ siwaju ọba, lẹ́yìn tí ó ba ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó yẹ, ó lè gba ohunkohun tí ó bá fẹ́ mú lọ láti ilé àwọn ayaba.

14. Yóo lọ sibẹ ní alẹ́, ní òwúrọ̀ yóo pada wá sí ilé keji tí àwọn ayaba ń lò, tí ó wà ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi, ìwẹ̀fà tí ó ń tọ́jú àwọn obinrin ọba. Kò tún ní pada lọ rí ọba mọ́, àfi bí inú ọba bá dùn sí i tí ó sì ranṣẹ pè é.

15. Nígbà tí ó tó àkókò fún Ẹsita, ọmọ Abihaili ẹ̀gbọ́n Modekai, láti lọ rí ọba, Ẹsita kò bèèrè nǹkankan ju ohun tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba tí ń tọ́jú àwọn ayaba, sọ fún un pé kí ó mú lọ. Ẹsita rí ojurere lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n rí i.

16. Wọ́n mú Ẹsita lọ sọ́dọ̀ ọba Ahasu-erusi ní ààfin rẹ̀ ní oṣù Tebeti, tíí ṣe oṣù kẹwaa, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀.

17. Ọba fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn obinrin yòókù lọ, ó sì rí ojurere ọba ju gbogbo àwọn wundia yòókù lọ. Ọba gbé adé lé e lórí, ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣiti.

18. Ọba bá se àsè ńlá fún àwọn olóyè ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ nítorí Ẹsita. Ó fún gbogbo eniyan ní ìsinmi, ó sì fún wọn ní ọpọlọpọ ẹ̀bùn.

19. Nígbà tí àwọn wundia péjọ ní ẹẹkeji, Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin.

20. Ṣugbọn Ẹsita kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀yà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Modekai ti pàṣẹ fún un, nítorí ó gbọ́ràn sí Modekai lẹ́nu, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe nígbà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.

21. Ní àkókò náà, nígbà tí Modekai jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin, meji ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà: Bigitana ati Tereṣi, ń bínú sí ọba, wọ́n sì ń dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba.

22. Ṣugbọn Modekai gbọ́ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ fún Ẹsita, ayaba, Ẹsita bá tètè lọ sọ fún ọba pé Modekai ni ó gbọ́ nípa ète náà tí ó sọ fún òun.

Ka pipe ipin Ẹsita 2