Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 8:18-36 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun.

19. Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún,

20. láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé.

21. Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa.

22. Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e.

23. Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa.

24. Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn.

25. Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun.

26. Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà,

27. ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà.

28. Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín.

29. Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.”

30. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu.

31. Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà.

32. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

33. Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui.

34. A ka gbogbo wọn, a sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́.

35. Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun.

36. Wọ́n fún àwọn aláṣẹ ati àwọn gomina tí ọba yàn fún àwọn ìgbèríko tí wọ́n wà ní òdìkejì odò ní ìwé àṣẹ tí ọba pa; àwọn aláṣẹ náà sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ati fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun.

Ka pipe ipin Ẹsira 8