Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 9:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.

17. Ó ní Farao sì tún ń gbé ara rẹ̀ ga sí àwọn eniyan òun, kò jẹ́ kí wọ́n lọ.

18. OLUWA ní, “Wò ó, níwòyí ọ̀la, n óo da yìnyín bo ilẹ̀, irú èyí tí kò sí ní ilẹ̀ Ijipti rí, láti ọjọ́ tí wọ́n ti tẹ̀ ẹ́ dó títí di òní yìí.

19. Nítorí náà, yára ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn ẹran rẹ tí wọ́n wà ninu pápá síbi ìpamọ́, nítorí pé yìnyín yóo rọ̀ sórí eniyan ati ẹranko tí ó bá wà ní pápá, tí wọn kò bá kó wọlé, gbogbo wọn ni yóo sì kú.”

20. Nítorí náà gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ OLUWA ninu àwọn iranṣẹ Farao pe àwọn ẹrú wọn wálé, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn wálé pẹlu.

21. Ṣugbọn àwọn tí wọn kò ka ọ̀rọ̀ OLUWA sí fi àwọn ẹrú ati àwọn ohun ọ̀sìn wọn sílẹ̀ ninu pápá.

22. OLUWA sọ fún Mose pé, “Na ọwọ́ rẹ sójú ọ̀run, kí yìnyín lè bọ́ kí ó sì bo ilẹ̀ Ijipti, ati eniyan, ati ẹranko, ati gbogbo ewéko inú ìgbẹ́.”

23. Mose bá na ọ̀pá rẹ̀ sójú ọ̀run, Ọlọrun sì da ààrá ati yìnyín ati iná bo ilẹ̀, Ọlọrun sì rọ̀jò yìnyín sórí ilẹ̀ Ijipti.

24. Yìnyín ń bọ́, mànàmáná sì ń kọ yànràn ninu yìnyín náà. Yìnyín náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́; kò tíì sí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti ìgbà tí ó ti di orílẹ̀-èdè.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 9