Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 9:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun tún sọ fún Mose pé kí ó wọlé tọ Farao lọ, kí ó sì sọ fún un pé kí ó gbọ́ ohun tí òun OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu wí, kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ sìn òun.

2. Ati pé, bí ó bá kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n lọ,

3. àjàkálẹ̀ àrùn yóo ti ọwọ́ òun OLUWA wá sórí gbogbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí wọ́n wà ní pápá, ati àwọn ẹṣin rẹ̀, ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ati àwọn ràkúnmí rẹ̀, ati àwọn agbo mààlúù rẹ̀, ati àwọn agbo aguntan rẹ̀.

4. Ó ní, Ṣugbọn òun yóo ya àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti, ẹyọ kan ṣoṣo kò ní kú ninu gbogbo àwọn ẹran tíí ṣe ti àwọn ọmọ Israẹli.

5. OLUWA bá dá àkókò kan, ó ní, “Ní ọ̀la ni èmi OLUWA, yóo ṣe ohun tí mo wí yìí ní ilẹ̀ Ijipti.”

6. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji OLUWA ṣe bí ó ti wí; gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ará Ijipti kú, ṣugbọn ẹyọ kan ṣoṣo kò kú ninu ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli.

7. Farao bá ranṣẹ lọ wo àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli, ó sì rí i pé ẹyọ kan kò kú ninu wọn. Sibẹsibẹ ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan náà lọ.

8. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé kí wọn bu ẹ̀kúnwọ́ eérú bíi mélòó kan ninu ẹbu, kí Mose dà á sí ojú ọ̀run lójú Farao,

9. yóo sì di eruku lẹ́búlẹ́bú lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti, yóo di oówo tí yóo máa di egbò lára eniyan ati ẹranko, ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

10. Mose ati Aaroni bá bu eérú ninu ẹbu, wọ́n dúró níwájú Farao. Mose da eérú náà sókè sí ojú ọ̀run, eérú náà bá di oówo tí ń di egbò lára eniyan ati ẹranko.

11. Àwọn pidánpidán kò lè dúró níwájú Mose, nítorí pe oówo bo àwọn náà ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ Ijipti.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 9