Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 8:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà tí Farao rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọ́ náà kú tán, ọkàn rẹ̀ tún le, kò sì ṣe ohun tí Mose ati Aaroni wí mọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

16. OLUWA rán Mose pé, kí ó sọ fún Aaroni pé kí ó na ọ̀pá rẹ̀ jáde, kí ó sì fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, kí gbogbo rẹ̀ sì di iná orí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

17. Wọ́n ṣe bí OLUWA ti wí; Aaroni na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀, ó fi lu erùpẹ̀ ilẹ̀, iná sì bo àwọn eniyan ati àwọn ẹranko; gbogbo erùpẹ̀ ilẹ̀ sì di iná ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.

18. Àwọn pidánpidán náà gbìyànjú láti mú kí iná jáde pẹlu ọgbọ́n idán wọn, ṣugbọn wọn kò lè ṣe é. Iná bo gbogbo eniyan ati àwọn ẹranko.

19. Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.

20. OLUWA bá tún sọ fún Mose pé, “Dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, kí o lọ dúró de ọba Farao bí ó bá ti ń jáde lọ sétí odò, wí fún un pé, kí ó gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ sìn mí.

21. Wí fún un pé, mo ní, tí kò bá jẹ́ kí wọ́n lọ n óo da eṣinṣin bo òun ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan rẹ̀, àwọn ará ilé rẹ̀ ati ti àwọn ará Ijipti, orí ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé yóo sì kún fún ọ̀wọ́ eṣinṣin.

22. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà, èmi OLUWA yóo ya ilẹ̀ Goṣeni sọ́tọ̀, níbi tí àwọn eniyan mi ń gbé, kí ọ̀wọ́ eṣinṣin má baà lè débẹ̀, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA ní ayé yìí.

23. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi ààlà sí ààrin àwọn eniyan mi ati àwọn eniyan rẹ̀. Ní ọ̀la ni iṣẹ́ ìyanu náà yóo ṣẹ.”

24. OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀; ọ̀wọ́ eṣinṣin wọ inú ilé Farao ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Eṣinṣin sì ba ilẹ̀ náà jẹ́.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 8