Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 38:23-31 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, wà pẹlu rẹ̀. Oholiabu yìí mọ iṣẹ́ ọnà gan-an. Bákan náà, ó lè lo aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà.

24. Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

25. Fadaka tí àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn eniyan náà dájọ jẹ́ ọgọrun-un ìwọ̀n talẹnti, ati ẹẹdẹgbẹsan ìwọ̀n ṣekeli ó lé marundinlọgọrin (1,775), ìwọ̀n tí wọ́n máa ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwọn tí wọ́n kà ninu àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n dá wúrà ati fadaka ati idẹ yìí jọ.

26. Olukuluku àwọn tí wọ́n tó ọmọ ogún ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí wọ́n kà dá ìdajì ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan tí òfin wí, ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ilé OLUWA ni wọ́n sì fi wọ̀n ọ́n, iye àwọn eniyan tí wọ́n kà jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́, ati ẹgbẹtadinlogun ó lé aadọjọ (603,550).

27. Ọgọrun-un talẹnti fadaka yìí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ òpó ilé OLUWA ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn aṣọ títa. Ọgọrun-un talẹnti ni wọ́n lò láti ṣe ọgọrun-un ìtẹ́lẹ̀, talẹnti kọ̀ọ̀kan fún ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

28. Ninu ẹẹdẹgbẹsan ó lé marundinlọgọrin (1,775) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni ó ti ṣe àwọn ìkọ́ fún àwọn òpó náà, ara rẹ̀ ni ó yọ́ lé àwọn ìbòrí wọn, tí ó sì tún fi ṣe àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ fún aṣọ títa wọn.

29. Àwọn idẹ tí wọ́n dájọ jẹ́ aadọrin ìwọ̀n talẹnti ati ẹgbaa ó lé irinwo (2,400) ìwọ̀n ṣekeli.

30. Idẹ yìí ni ó lò láti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn ìlẹ̀kùn àgọ́ àjọ, ati pẹpẹ onídẹ, ati àwọn idẹ inú rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò ibi pẹpẹ náà.

31. Lára rẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó àgọ́ náà yípo ati àwọn èèkàn àgọ́ ati àwọn èèkàn àgbàlá inú rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 38