Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 26:21-37 BIBELI MIMỌ (BM)

21. ati ogoji ìtẹ́lẹ̀ fadaka, meji meji sí àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

22. Àkànpọ̀ igi mẹfa ni kí ó wà lẹ́yìn àgọ́ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.

23. Kí o sì ṣe àkànpọ̀ igi meji meji fún igun mejeeji ẹ̀yìn àgọ́ náà.

24. Jẹ́ kí àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun àgọ́ wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìsàlẹ̀, ṣugbọn kí o so wọ́n pọ̀ ní òkè ní ibi ìtẹ̀bọ̀ àkọ́kọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe àwọn àkànpọ̀ igi mejeeji tí wọ́n wà ní igun mejeeji.

25. Gbogbo àkànpọ̀ igi yóo jẹ́ mẹjọ, ìtẹ́lẹ̀ fadaka wọn yóo sì jẹ́ mẹrindinlogun, meji meji lábẹ́ àkànpọ̀ igi kọ̀ọ̀kan.

26. “Fi igi akasia ṣe igi ìdábùú mẹẹdogun; marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni àgọ́ náà,

27. marun-un fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ keji, marun-un yòókù fún àwọn àkànpọ̀ igi tí wọ́n wà ní ẹ̀yìn ní apá ìwọ̀ oòrùn.

28. Kí igi ìdábùú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àkànpọ̀ igi náà gùn láti ẹ̀gbẹ́ kinni dé ẹ̀gbẹ́ keji àgọ́ náà.

29. Yọ́ wúrà bo àwọn àkànpọ̀ igi náà, kí wọ́n sì ní àwọn òrùka wúrà kí wọ́n lè máa ti àwọn igi ìdábùú náà bọ̀ ọ́, yọ́ wúrà bo àwọn igi ìdábùú náà pẹlu.

30. Bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, ni kí o ṣe kọ́ àgọ́ náà.

31. “Ṣe aṣọ títa kan, tí ó jẹ́ aláwọ̀ aró, ati elése àlùkò, ati pupa, ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n ya àwòrán Kerubu sí i lára.

32. Gbé e kọ́ sórí òpó igi akasia mẹrin, tí ó ní ìkọ́ wúrà. Wúrà ni kí o yọ́ bo gbogbo òpó náà, kí wọ́n sì wà lórí ìtẹ́lẹ̀ fadaka mẹrin.

33. Lára àwọn àtẹ̀bọ̀ ni kí o fi àwọn aṣọ títa náà kọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí náà wọ inú ibi tí aṣọ títa náà wà, aṣọ títa yìí ni yóo ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò lára ibi mímọ́ jùlọ.

34. Fi ìtẹ́ àánú sórí àpótí ẹ̀rí ninu ibi mímọ́ jùlọ.

35. Kí o gbé tabili kalẹ̀ ní ọwọ́ òde aṣọ títa náà, kí ọ̀pá fìtílà wà ní apá ìhà gúsù àgọ́ náà, ní òdìkejì tabili náà, kí o sì gbé tabili náà kalẹ̀ ní apá àríwá.

36. “Fi aṣọ aláwọ̀ aró ati elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí létí ṣe aṣọ títa kan fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.

37. Ṣe òpó igi akasia marun-un fún aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà; wúrà ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn pẹlu, kí o sì ṣe ìtẹ́lẹ̀ idẹ marun-un fún wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 26