Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 23:19-24 BIBELI MIMỌ (BM)

19. “Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá.“O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀.

20. “Wò ó, mo rán angẹli kan ṣiwaju rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ọ̀nà rẹ, ati láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti tọ́jú fún ọ.

21. Máa fetí sí ohun tí angẹli náà bá sọ fún ọ, kí o sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, má ṣe fi agídí ṣe ìfẹ́ inú rẹ lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí pé èmi ni mo rán an, kò sì ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.

22. Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ.

23. Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run,

24. o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 23