Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 23:1-17 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “O kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ sí àhesọ tí kò ní òtítọ́ ninu. O kò gbọdọ̀ bá eniyan burúkú pa ìmọ̀ pọ̀ láti jẹ́rìí èké.

2. O kò gbọdọ̀ bá ọ̀pọ̀ eniyan kẹ́gbẹ́ láti ṣe ibi, tabi kí o tẹ̀lé ọ̀pọ̀ eniyan láti jẹ́rìí èké tí ó lè yí ìdájọ́ po.

3. O kò gbọdọ̀ ṣe ojuṣaaju sí talaka lórí ẹjọ́ rẹ̀.

4. “Bí o bá pàdé akọ mààlúù ọ̀tá rẹ tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tí ń ṣìnà lọ, o níláti fà á pada wá fún un.

5. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀.

6. “O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́.

7. O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre.

8. O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi.

9. “O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti.

10. “Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀.

11. Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu.

12. “Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe iṣẹ́, ṣugbọn ní ọjọ́ keje, kí o sinmi; àtìwọ ati akọ mààlúù rẹ, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ; kí ara lè tu ọmọ iranṣẹbinrin rẹ ati àlejò rẹ.

13. “Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ.

14. “Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún.

15. O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.

16. “O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ.“Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè.

17. Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 23