Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 21:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀,

6. olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé.

7. “Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin.

8. Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un.

9. Bí ó bá fẹ́ ẹ sọ́nà fún ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ó gbọdọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ gan-an.

10. Bí ó bá fẹ́ aya mìíràn fún ara rẹ̀, kò gbọdọ̀ dín oúnjẹ ẹrubinrin yìí kù, tabi aṣọ rẹ̀ tabi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya.

11. Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun.

12. “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà.

13. Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín.

14. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á.

15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà.

16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.

17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 21