Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 19:12-25 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á.

13. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.”

14. Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.

15. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.”

16. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì.

17. Mose bá kó àwọn eniyan náà jáde láti pàdé Ọlọrun, wọ́n sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè.

18. Èéfín bo gbogbo òkè Sinai mọ́lẹ̀, nítorí pé ninu iná ni OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀, ọ̀wọ̀n èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ bí ọ̀wọ̀n èéfín iná ìléru ńlá, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.

19. Bí fèrè ti ń dún kíkankíkan tí dídún rẹ̀ sì ń gòkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni Mose ń sọ̀rọ̀, Ọlọrun sì ń fi ààrá dá a lóhùn.

20. OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ó dúró ní ṣóńṣó òkè náà, ó pe Mose sọ́dọ̀, Mose sì gòkè tọ̀ ọ́ lọ.

21. OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun.

22. Ati pé, kí àwọn alufaa tí yóo súnmọ́ ibi tí OLUWA wà, ya ara wọn sí mímọ́, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.”

23. Mose bá dá OLUWA lóhùn pé, “OLUWA, àwọn eniyan wọnyi kò lè gun òkè Sinai wá, nítorí pé ìwọ náà ni o pàṣẹ pé kí á pààlà yí òkè náà po, kí á sì yà á sí mímọ́.”

24. OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.”

25. Mose bá sọ̀kalẹ̀ lọ bá àwọn eniyan náà, ó sì jíṣẹ́ fún wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 19