Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 16:2-14 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni ninu aṣálẹ̀,

3. wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.”

4. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wò ó, n óo rọ̀jò oúnjẹ fún yín láti ọ̀run. Kí àwọn eniyan máa jáde lọ ní ojoojumọ, kí wọ́n sì máa kó ìwọ̀nba ohun tí wọn yóo jẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. N óo fi èyí dán wọn wò, kí n fi mọ̀ bóyá wọn yóo máa tẹ̀lé òfin mi tabi wọn kò ní tẹ̀lé e.

5. Nígbà tí ó bá di ọjọ́ kẹfa, kí wọ́n kó oúnjẹ wálé kí ó tó ìlọ́po meji èyí tí wọn ń kó ní ojoojumọ.”

6. Mose ati Aaroni bá sọ fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́ òní ni ẹ óo mọ̀ pé OLUWA ló mú yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.

7. Nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, ẹ óo rí ògo OLUWA, nítorí ó ti gbọ́ kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i. Kí ni àwa yìí jẹ́, tí ẹ óo fi máa kùn sí wa?”

8. Mose ní, “OLUWA tìkararẹ̀ ni yóo fún yín ní ẹran ní ìrọ̀lẹ́, ati burẹdi ní òwúrọ̀. Ẹ óo jẹ àjẹyó, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn sí i; nítorí pé kí ni àwa yìí jẹ́? Gbogbo kíkùn tí ẹ̀ ń kùn, àwa kọ́ ni ẹ̀ ń kùn sí, OLUWA gan-an ni ẹ̀ ń kùn sí.”

9. Mose sọ fún Aaroni pé, “Sọ fún gbogbo ìjọ eniyan Israẹli pé, kí wọ́n súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ OLUWA, nítorí pé ó ti gbọ́ gbogbo kíkùn wọn.”

10. Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu.

11. OLUWA bá wí fún Mose pé,

12. “Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn, wí fún wọn pé, ‘Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ óo máa jẹ ẹran, ní òwúrọ̀, ẹ óo máa jẹ burẹdi ní àjẹyó. Nígbà náà ni ẹ óo tó mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.’ ”

13. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ẹyẹ àparò fò dé, wọ́n sì bo gbogbo àgọ́ náà; nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ìrì sẹ̀ bo gbogbo àgọ́ náà.

14. Nígbà tí ìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n rí i tí kinní funfun kan tí ó dàbí ìrì dídì bo ilẹ̀ ní gbogbo aṣálẹ̀ náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 16