Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 10:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá pe Mose, ó ní, “Wọlé tọ Farao lọ, nítorí pé mo tún ti mú ọkàn rẹ̀ le, ati ti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, kí n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu mi láàrin wọn.

2. Kí ẹ̀yin náà sì lè sọ fún àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ yín, irú ohun tí mo fi ojú wọn rí, ati irú iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe láàrin wọn; kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”

3. Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun.

4. Nítorí pé bí o bá kọ̀, tí o kò jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ, ó ní òun yóo mú kí eṣú wọ ilẹ̀ rẹ lọ́la.

5. Àwọn eṣú náà yóo sì bo gbogbo ilẹ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní rí ilẹ̀ rárá, wọn yóo sì jẹ gbogbo ohun tí ó ṣẹ́kù tí yìnyín kò pa, wọn yóo jẹ gbogbo igi rẹ tí ó wà ninu pápá oko.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 10