Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 5:18-27 BIBELI MIMỌ (BM)

18. “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe panṣaga.

19. “ ‘O kò gbọdọ̀ jalè.

20. “ ‘O kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí aládùúgbò rẹ.

21. “ ‘O kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya ẹlòmíràn, tabi ilé rẹ̀, tabi oko rẹ̀, tabi iranṣẹkunrin rẹ̀, tabi iranṣẹbinrin rẹ̀, tabi akọ mààlúù rẹ̀, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, tabi ohunkohun tíí ṣe ti ẹlòmíràn.’

22. “Àwọn òfin tí OLUWA fún gbogbo yín nìyí, nígbà tí ẹ fi péjọ lẹ́sẹ̀ òkè, tí ó fi fi ohùn rara ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná ati ìkùukùu, ati òkùnkùn biribiri. Àwọn òfin yìí nìkan ni ó fun yín, kò sí òmíràn lẹ́yìn wọn, ó kọ wọ́n sára tabili òkúta meji, ó sì kó wọn fún mi.

23. “Nígbà tí ẹ gbọ́ ohùn láti inú òkùnkùn biribiri, tí iná sì ń jó lórí òkè, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà yín ati àwọn àgbààgbà wá sọ́dọ̀ mi;

24. wọ́n ní, ‘OLUWA Ọlọrun wa ti fi títóbi ati ògo rẹ̀ hàn wá, a sì ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láàrin iná. Lónìí ni a rí i tí Ọlọrun bá eniyan sọ̀rọ̀, tí olúwarẹ̀ sì tún wà láàyè.

25. Nítorí náà, kí ló dé tí a óo fi kú? Nítorí pé, iná ńlá yìí yóo jó wa run; bí a bá tún gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa sí i, a óo kú.

26. Nítorí pé ninu gbogbo ẹ̀dá alààyè, ta ni ó tíì gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun alààyè rí láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́ ọ yìí, tí ó sì wà láàyè?

27. Ìwọ Mose, súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí o sì gbọ́ gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun yóo sọ, kí o wá sọ fún wa, a óo sì ṣe é.’

Ka pipe ipin Diutaronomi 5