Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 5:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbọ́ àwọn ìlànà ati àwọn òfin tí n óo kà fun yín lónìí; ẹ kọ́ wọn, kí ẹ sì rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀lé wọn.

2. OLUWA Ọlọrun wa bá wa dá majẹmu kan ní òkè Horebu.

3. Kì í ṣe àwọn baba wa ni OLUWA bá dá majẹmu yìí, ṣugbọn àwa gan-an tí a wà láàyè níhìn-ín lónìí ni ó bá dá majẹmu náà.

4. OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ lojukooju lórí òkè ní ààrin iná.

5. Èmi ni mo dúró láàrin ẹ̀yin ati OLUWA nígbà náà, tí mo sì sọ ohun tí OLUWA wí fun yín; nítorí ẹ̀rù iná náà ń bà yín, ẹ kò sì gun òkè náà lọ.“OLUWA ní,

6. ‘Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà:

7. “ ‘O kò gbọdọ̀ bọ oriṣa, èmi OLUWA ni kí o máa sìn.

8. “ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.

9. O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

Ka pipe ipin Diutaronomi 5