Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 30:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun iṣẹ́ ọwọ́ yín lọpọlọpọ, ati àwọn ọmọ yín; àwọn ọmọ mààlúù yín, ati àwọn ohun ọ̀gbìn yín, nítorí inú OLUWA yóo tún dùn láti bukun yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe inú dídùn sí àwọn baba yín,

10. bí ẹ bá gbọ́ ti OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ mọ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin yìí, tí ẹ bá sì yipada tọkàntọkàn.

11. “Nítorí pé òfin tí mo fun yín lónìí kò le jù fun yín, kì í sìí ṣe ohun tí apá yín kò ká.

12. Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

13. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

14. Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é.

15. “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀.

16. Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín.

17. Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

18. mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 30